Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 70:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là, Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

2. Kí àwọn tí ń wá ọkàn mikí a dojú tì wọ́n, kí wọn sì dààmú;kí àwọn tó ń wá ìparun miyí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.

3. Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrèìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Áà! Áà!”

4. Ṣùgbọ́n kí àwọn tí o ń wà ọ ó máa yọ̀kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa Rẹ,kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà Rẹ máa wí pé,“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

Ka pipe ipin Sáàmù 70