Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 7:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. kí wọn ó má bá à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìúnwọn a ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gba mí.

3. Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyítí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi

4. Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mití mo ja ọ̀ta mí lólè láìnídìí:

5. Nígbà náà jẹ́ kí ọ̀ta mi le mi kí wọn sì mú mi;jẹ́ kí òun kí ó tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela

6. Dìde, Olúwa, nínú ìbínú Rẹ;dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀ta mi.Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.

7. Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yí ká.Jọba lórí wọn láti òkè wá;

8. Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.

Ka pipe ipin Sáàmù 7