Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 69:22-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó dí ìkẹ́kùnni iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹfún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

23. Kí ojú wọn kií ó ṣókùnkùn kí wọ́n má ṣe ríran,kí eyín wọn di títẹ̀ títí láé.

24. Tú ìbínú Rẹ jáde sí wọn;kí ìbínú gbígbóná Rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

25. Kí ibùjókòó wọn di ahoro;kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

26. Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe

27. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà Rẹ.

28. Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyèkí á má kà wọn pẹ̀lú àwọn olódodo.

29. Ṣùgbọ́n talákà àti ẹni-ìkáánú ni èmí,Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà Rẹ gbé mi lékè.

30. Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run gaèmi yóò fí ọpẹ́ gbé orúkọ Rẹ̀ ga.

31. Eléyìí tẹ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo Rẹ̀ àti bàtà Rẹ̀.

32. Àwọn òtòsì yóò rí wọn yóò sì yọ̀:Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yin yóò sì wà láàyè!

33. Olúwa, gbọ́ ti aláìníkí o sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

34. Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,òkun àti àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀,

35. Nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Síónì làyóò sì tún àwọn ìlú Júdà wọ̀nyí kọ́.Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀,kí wọn ó lè máa níi ni ilẹ̀ ìní

Ka pipe ipin Sáàmù 69