Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 69:20-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́ wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́Mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,mo ń wá olùtùnú, Ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

21. Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,àti ní òungbẹ mi, wọn fi ọtí kíkan fún mi.

22. Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó dí ìkẹ́kùnni iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹfún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

23. Kí ojú wọn kií ó ṣókùnkùn kí wọ́n má ṣe ríran,kí eyín wọn di títẹ̀ títí láé.

24. Tú ìbínú Rẹ jáde sí wọn;kí ìbínú gbígbóná Rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

25. Kí ibùjókòó wọn di ahoro;kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

26. Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe

27. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà Rẹ.

28. Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyèkí á má kà wọn pẹ̀lú àwọn olódodo.

29. Ṣùgbọ́n talákà àti ẹni-ìkáánú ni èmí,Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà Rẹ gbé mi lékè.

30. Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run gaèmi yóò fí ọpẹ́ gbé orúkọ Rẹ̀ ga.

31. Eléyìí tẹ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo Rẹ̀ àti bàtà Rẹ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 69