Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 69:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Dá mí lóhùn, Olúwa nínú ìṣeun ìfẹ́ Rẹ;nínú ọ̀pọ̀ àánú Rẹ yípadà sí mi.

17. Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ:yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.

18. Súnmọ́ tòsí kí ó sì gbà mí là;rà mí padà nítorí àwọn ọ̀ta mi.

19. Ìwọ tí mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;Gbogbo àwọn ọ̀ta mi wà níwájú Rẹ̀.

20. Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́ wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́Mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,mo ń wá olùtùnú, Ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

21. Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,àti ní òungbẹ mi, wọn fi ọtí kíkan fún mi.

22. Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó dí ìkẹ́kùnni iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹfún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

Ka pipe ipin Sáàmù 69