8. Ilẹ̀ mi títí,àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,níwájú Ọlọ́run,ẹni Sínáì,níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
9. Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;ìwọ tu ilé inú Rẹ̀ lára nígbà tí ó Rẹ̀ ẹ́ tan.
10. Àwọn ènìyàn Rẹ tẹ̀dó ṣíbẹ̀nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní Rẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
11. Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí o ń ròyìn Rẹ.
12. “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;Obìnrín tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13. Nígbà tí ẹ̀yin sùn láàrin àwọn àgọ́ iná,nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí apá àdàbà ti a bò ní sílífa.”
14. Nígbà ti Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,ó dàbí òjò dídi ní Salímónì.
15. Òkè Básánì jẹ́ òkè Ọlọ́run;òkè tí ó ní orí púpọ̀ ní òkè Básánì.
16. Kí ló dé ti ẹ̀yin fi ń lára,ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jọbaníbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?