30. Bá àwọn ẹranko búburú wí,tí ń gbé láàrin ìkoọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúùpẹ̀lú àwọn ọmọ màlúùtítí olúkúlùkù yóò fi forí balẹ̀ pẹ̀lú ìwọn fàdákà:tú àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe inú dídùn si ogun ká
31. Àwọn ọmọ aládé yóò wá láti Éjíbítì;Jẹ́ kí Etiópíà na ọwọ́ Rẹ̀ sí Ọlọ́run.
32. Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela
33. Sí ẹni tí ń gún ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,tó ń fọhùn Rẹ̀, ohùn ńlá.
34. Kéde agbára Ọlọ́run,ọlá ńlá Rẹ̀ wà lórí Ísírẹ́lìtí agbára Rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
35. Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ Rẹ;Ọlọ́run Ísírẹ́lìfi agbára àti òkun fún àwọn ènìyàn Rẹ̀.Olùbùkún ní Ọlọ́run!