Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 68:25-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Àwọn akọrin ní íwájú,tí wọn ń lu tanborí

26. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Ísírẹ́lì wá.

27. Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Bẹ́ńjámínì wà, tí o ń darí wọn,níbẹ̀ ni àwọn ọmọ aládé Júdà,níbẹ̀ ni àwọn ọmọ aládé Sébúlúnì àti tí Náfútàlì.

28. Pàsẹ agbára Rẹ, Ọlọ́run;fi agbára Rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀.

29. Nítorí tẹ́ḿpìlì Rẹ ni Jérúsálẹ́mùàwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.

30. Bá àwọn ẹranko búburú wí,tí ń gbé láàrin ìkoọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúùpẹ̀lú àwọn ọmọ màlúùtítí olúkúlùkù yóò fi forí balẹ̀ pẹ̀lú ìwọn fàdákà:tú àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe inú dídùn si ogun ká

31. Àwọn ọmọ aládé yóò wá láti Éjíbítì;Jẹ́ kí Etiópíà na ọwọ́ Rẹ̀ sí Ọlọ́run.

32. Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela

33. Sí ẹni tí ń gún ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,tó ń fọhùn Rẹ̀, ohùn ńlá.

34. Kéde agbára Ọlọ́run,ọlá ńlá Rẹ̀ wà lórí Ísírẹ́lìtí agbára Rẹ̀ wà lójú ọ̀run.

35. Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ Rẹ;Ọlọ́run Ísírẹ́lìfi agbára àti òkun fún àwọn ènìyàn Rẹ̀.Olùbùkún ní Ọlọ́run!

Ka pipe ipin Sáàmù 68