Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 68:17-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́runẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrin wọn ní Sínáì ni ibi mímọ́ Rẹ̀.

18. Ìwọ ti gòkè sí ibi gígaìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbékùn lọ;ìwọ ti gbà ẹ̀bùn fún ènìyàn:nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,Kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.

19. Olùbùkún ni Ọlọ́run,sí Ọlọ́run Olùgbàlà wa,ẹni tí ó ń fi ojojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela

20. Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlààti sí Olúwa Ọlọ́run ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.

21. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá Rẹ̀,àti agbárí onirun àwọn tó ń tẹ̀ṣíwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn

22. Olúwa wí pé, “Èmi o mú wọn wá láti Báṣánì;èmi ó mú wọn wá láti ibú omi òkun,

23. Kí ẹṣẹ̀ Rẹ̀ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá Rẹ̀,àti ahọ́n àwọn ajá Rẹ̀ ní ìpín ti wọn lára àwọn ọ̀tá Rẹ.”

24. Wọn ti rì ìrìn Rẹ, Ọlọ́run,irin Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ Rẹ̀.

25. Àwọn akọrin ní íwájú,tí wọn ń lu tanborí

26. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Ísírẹ́lì wá.

27. Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Bẹ́ńjámínì wà, tí o ń darí wọn,níbẹ̀ ni àwọn ọmọ aládé Júdà,níbẹ̀ ni àwọn ọmọ aládé Sébúlúnì àti tí Náfútàlì.

Ka pipe ipin Sáàmù 68