Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 68:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Àwọn ènìyàn Rẹ tẹ̀dó ṣíbẹ̀nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní Rẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.

11. Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí o ń ròyìn Rẹ.

12. “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;Obìnrín tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.

13. Nígbà tí ẹ̀yin sùn láàrin àwọn àgọ́ iná,nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí apá àdàbà ti a bò ní sílífa.”

14. Nígbà ti Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,ó dàbí òjò dídi ní Salímónì.

15. Òkè Básánì jẹ́ òkè Ọlọ́run;òkè tí ó ní orí púpọ̀ ní òkè Básánì.

16. Kí ló dé ti ẹ̀yin fi ń lára,ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jọbaníbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?

17. Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́runẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrin wọn ní Sínáì ni ibi mímọ́ Rẹ̀.

18. Ìwọ ti gòkè sí ibi gígaìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbékùn lọ;ìwọ ti gbà ẹ̀bùn fún ènìyàn:nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,Kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.

19. Olùbùkún ni Ọlọ́run,sí Ọlọ́run Olùgbàlà wa,ẹni tí ó ń fi ojojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela

Ka pipe ipin Sáàmù 68