Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 68:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kí Ọlọ́run kí o dìde, kí àwọn ọ̀ta Rẹ̀ kí ó fọ́nká;kí àwọn ọ̀ta Rẹ̀ kí ó sá níwájú Rẹ̀.

2. Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,kí ó fẹ́ wọn lọ;bí ìdà tí i yọ́ níwájú iná,kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.

3. Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùnkí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.

4. Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,ẹ kọrin ìyìn síi,ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń ré kọjá ní ihà.JAH ni orúkọ Rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Rẹ̀.

5. Baba àwọn aláìní baba àti Onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ni ibùgbéRẹ̀ mímọ́

6. Ọlọ́run gbé ẹni òfokálẹ̀ nínú ìdílé,ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orinṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.

7. Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn Rẹ̀, Ọlọ́run,tí ń kọjá lọ láàrin ihà, Sela

Ka pipe ipin Sáàmù 68