Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 66:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ Rẹ̀!Nípa ọ̀pọ̀ agbára Rẹ ni àwọn ọ̀táRẹ yóò fi sìn ọ́.

4. Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ.” Sela

5. Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,Iṣẹ́ Rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!

6. O yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn inú omi kọjá,níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú Rẹ.

7. O ń jọba títí láé nípa agbára Rẹ̀,ojú Rẹ̀ ń wò orílẹ̀ èdèkí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela

8. Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohun ìyìn Rẹ̀;

9. O ti dá ààbò bo ẹ̀mí wakò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí o yẹ̀

10. Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, Dan wa wò;ìwọ dán wa bí a tí ń Dan fàdákà wo

11. Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀no sì di ẹ̀rù lé ẹ̀yìn wa

Ka pipe ipin Sáàmù 66