Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 66:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run, gbogbo ayé!

2. Ẹ kọrin ọ̀lá orúkọ Rẹ̀;Ẹ fún un ní ìyìn, ògo,

3. Ẹ wí fún Ọlọ́run “pé,ìwọ ti ní ẹ̀rù tó nínú iṣẹ́ Rẹ̀!Nípa ọ̀pọ̀ agbára Rẹ ni àwọn ọ̀táRẹ yóò fi sìn ọ́.

4. Gbogbo ayé ń wólẹ̀ fún ọ;wọn ń kọrin ìyìn sí ọ,wọ́n ń kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ.” Sela

5. Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,Iṣẹ́ Rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!

6. O yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn inú omi kọjá,níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú Rẹ.

7. O ń jọba títí láé nípa agbára Rẹ̀,ojú Rẹ̀ ń wò orílẹ̀ èdèkí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela

Ka pipe ipin Sáàmù 66