Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 65:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;ìwọ mú ní ọ̀rọ̀ púpọ̀.Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kún fún omiláti pèsè ọkàn fún àwọn ènìyàn,nítorí ibẹ̀ ní ìwọ ti yàn án.

10. Ìwọ fi ìrinmi sí aporo Rẹìwọ tẹ́ ògúlùtù Rẹ;ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ Rẹ rọ̀o sì bùkún ọ̀gbìn Rẹ.

11. Iwọ fi oore Rẹ de ọdún ni adé,ọ̀rá ń kan ni ipa-ọ̀nà Rẹ

12. Pápá-tútù ni ihà ń kán: àwọn òkè kékèké fi ayọ̀ di ara wọn ni àmùrè.

13. Agbo ẹran ni a fi wọ pápá tútù náà, ni asọ; àfonífojì ni a fi ọkà bò mọ́lẹ̀,wọn hó fún ayọ̀, wọn ń kọrin pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Sáàmù 65