Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 65:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìyìn ń dúró dè ọ́, Ọlọ́run, ni Síónì;sì ọ ni a o mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.

2. Ìwọ tí o ń gbọ́ àdúrà,gbogbo ènìyàn yóò sì wá sọ́dọ̀ Rẹ.

3. Ọ̀ràn àìṣedédé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni!Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò

4. Ìbùkún ni fún àwọn tí o yàntí o mú wa láti máa gbé àgọ́ Rẹ!A tẹ wá lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere inú ilé Rẹ,ti tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ.

5. Ìwọ dá wa lóhùn pẹ̀lú ohùn ìyanu ti òdodo,Ọlọ́run olùgbàlà wa,ìrètí gbogbo òpin ayéàti àwọn tí ó jìnnà nínú òkun,

Ka pipe ipin Sáàmù 65