Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 64:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Wọ́n tafà ní kọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:wọ́n tafà sí lojijì, wọn kò sì bẹ̀rù.

5. Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹ́kun sílẹ̀ ní kọ̀kọ̀wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”

6. Wọ́n gbìmọ̀ àìsòdodo, wọn wí pé,“A wa ti parí èrò tí a gbà tán”lóòtọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

7. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.

8. Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́nGbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.

Ka pipe ipin Sáàmù 64