Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 63:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,nígbà gbogbo ní mo ń ṣàfẹ́rí Rẹóùngbẹ́ Rẹ ń gbẹ ọkàn miara mi fà sí ọ,ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ ti ń ṣàárẹ̀níbi tí kò sí omi

2. Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́mo rí agbára àti ògo Rẹ.

3. Nítorí ìfẹ́ Rẹ dára ju ayé lọ,ètè mi yóò fògo fún ọ.

4. Èmi o yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè,èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ Rẹ.

5. A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ.

6. Nígbà tí mo rántí Rẹ lórí ìbusùn mi;èmi ń ronú Rẹ títí iṣọ́ òru.

7. Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,mo kọrin níbi òjijì-ìyẹ́ apá Rẹ.

8. Ọkàn mí fà sí ọ:ọwọ́ ọ̀tún Rẹ gbé mi ró.

9. Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ní a ó parun;wọn o sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.

10. Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubúwọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 63