Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 62:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ẹ̀yin ó ti máa rọ́lù ènìyàn kan pẹ́ tó?Gbogbo yín ni ó fẹ pa á,bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀ àti bí ọgbà tí ń wó lọ?

4. Kìkì èró wọn ni láti bì ṣubúkúrò nínú ọlá Rẹ̀;inú wọn dùn sí irọ́.Wọn ń fi ẹnu wọn súre,ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn nínú ọkàn wọn. Sela

5. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmí wà, ìwọ Ọlọ́run mi.Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ.

6. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;Òun ni ààbò mi, a kí yóò sí mi nípò.

7. Ìgbàlà mi àti ògo mí dúró nínú Ọlọ́run;Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 62