Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 61:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;Tẹ́tí sí àdúrà mi.

2. Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.

3. Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,ilé ìsọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

4. Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ Rẹ títí láékí ń sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá Rẹ.

5. Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ Rẹ̀.

6. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí o gùn,ọdùn Rẹ̀ fún ìrandíran.

7. Kí o máa jọba níwájú Ọlọ́run títí láé;pèsè àánú àti òtítọ́ Rẹ̀ tí yóò máa ṣe ìtọ́ju Rẹ.

8. Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ Rẹ títí láékí ń san ẹ̀jẹ́ mí ní ojoojúmọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 61