Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 60:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ tí kọ̀ wá sílẹ̀,Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa káìwọ ti bínú nísìnsín yìí, tún ara Rẹ yípadà sí wá.

2. Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;mú fífọ́ Rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mi.

3. Ìwọ ti fi ìgbà ewu hàn àwọn ènìyàn Rẹ;Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wa gbọ́n-ọ́ngbọ́n-ọ́n.

4. Àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ní ìwọ fi ọ̀págun fúnkí a lè fíhàn nítorí òtítọ́. Sela

5. Fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́,kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.

Ka pipe ipin Sáàmù 60