Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 60:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ tí kọ̀ wá sílẹ̀,Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa káìwọ ti bínú nísìnsín yìí, tún ara Rẹ yípadà sí wá.

2. Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;mú fífọ́ Rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mi.

3. Ìwọ ti fi ìgbà ewu hàn àwọn ènìyàn Rẹ;Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wa gbọ́n-ọ́ngbọ́n-ọ́n.

4. Àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ ní ìwọ fi ọ̀págun fúnkí a lè fíhàn nítorí òtítọ́. Sela

5. Fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ gbà wá kí ó sì ràn wá lọ́wọ́,kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.

6. Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ Rẹ̀:“Ní ayọ̀, èmi ó pín ṣèkémù jádeèmi o sì wọ̀n àfonífojì ṣúkótù.

7. Tèmi ni Gílíádì, tèmi sì ni Mánásè;Éfúráímù ni àsìbórì mi,Júdà sì ní ọ̀pá àṣẹ mi.

8. Móábù ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,lórí Édómù ní mo bọ́ bàtà mi sí;lórí fìlísitinì ni mo kígbe ayọ̀.”

9. Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Édómù?

10. Kí ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?

Ka pipe ipin Sáàmù 60