Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 59:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,kí àwọn ènìyàn mí má ba à gbàgbé.Nínú agbára Rẹ̀, jẹ́ kí wọ́n máa rìn kiri,kí ó sì Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,ni ọ̀rọ̀ ètè wọn,kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.Nítorí ẹ̀gàn àti èké tí wọn ń sọ,

13. Pa wọn run nínú ìbínú,run wọ́n di ìgbà tí wọ́n kò ní sí mọ́.Nígbà náà ní yóò di mímọ̀ dé òpin ayépé Ọlọ́run jọba lórí Jákọ́bù. Sela

14. Wọ́n padà ní àsálẹ́,wọn ń gbó bí àwọn ajáwọ́n ń rìn ìlú náà káàkiri.

15. Wọ́n ń rín kiri fún oúnjẹwọn sì ń yán nígbà tí wọn kò yó.

16. Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára Rẹ,ń ó kọrin ìfẹ́ Rẹ ní òwúrọ̀;nítorí ìwọ ni ààbò mi,ibi ìsádì mi ní ìgbà ìpọ́njú.

17. Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ;ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 59