Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 58:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọ̀rọ̀ wọn dà bí ọ̀rọ̀ ejò,gẹ́gẹ́ bí ti sèbé tí ó dítí Rẹ̀,wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara Rẹ̀ ni etí

5. Tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atinilójú,bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

6. Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;ní ẹnu wọnká ọ̀gan àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.

7. Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń ṣàn lọ;nígbà tí ó bá fa ọfà Rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.

8. Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí Rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbébí ọmọ ti oṣu Rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí òòrùn.

9. Kí ìkòkò yín kì o tó mọ̀ ìgbóná ẹ̀gún;ìbá tutù, ìbá ma jò, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.

10. Olódodo yóò yọ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọnnígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.

11. Àwọn ènìyàn yóò wí pé,“lóòtọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;lóòtọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

Ka pipe ipin Sáàmù 58