Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 56:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.

6. Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n baWọn ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ miwọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.

7. Wọ́n ha le mú un jẹ gbé?Ní ìbínú Rẹ, Ọlọ́run, wó àwọn ènìyàn yìí lulẹ̀ Ọlọ́run!

8. Kọ ẹkún mi sílẹ̀;kó omije mi sí ìgò Rẹwọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ Rẹ bí?

9. Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndànígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́nípa èyí ní mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi

10. Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ Rẹ̀nínú Olúwa, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ Rẹ̀:

11. Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:ẹ̀rù kì yóò bà míkí ni ènìyàn le ṣe sí mi?

12. Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ Rẹ Ọlọ́run:èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.

13. Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikúàti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́runní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.

Ka pipe ipin Sáàmù 56