Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 55:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Kí ikú kí ó dé bá wọn,Kí wọn ó lọ láàyè sí isà òkú,Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16. Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run; Olúwa yóò sì gbà mí.

17. Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sánèmi sunkún jáde nínú ìpọ́njú,o sì gbọ́ ohùn mi.

18. Ó rà mí padà láìléwukúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.

19. Ọlọ́run yóò gbọ́ yóò sì pọ́n wọn lójúàní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbà a nì—SelaNítorí tí wọn kò ní àyípadà,tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20. Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ Rẹ̀;ó ti bá májẹ̀mú Rẹ̀ jẹ́.

21. Ọ̀rọ̀ ẹnu Rẹ̀ kúnná ju òrí àmọ́,ṣùgbọ́n ogun ija wà ni àyà Rẹ̀;ọ̀rọ̀ Rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,ṣùgbọ́n idà fífà yọ ní wọn.

22. Gbé ẹrù Rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwayóò sì mú ọ dúró;òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.

23. Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá miwá sí ihò ìparun;Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tànkì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Ka pipe ipin Sáàmù 55