Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 55:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ọ̀sán àti oru ní wọ́n fí ń rìn gbogbo odi kiri;àrankàn àti èébú wà láàrin Rẹ̀.

11. Ìwà búburú ń bẹ ní àárin Rẹ̀;ìdẹ́rùbà àti irọ́ kò kúrò ní ìgboro Rẹ̀.

12. Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,èmi yóò fara mọ́ ọn;tí ọ̀ta bá gbé ara Rẹ̀ ga sími,èmi ibá sá pamọ́ fún un.

13. Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó sún mọ́ mi,

14. pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádún adùn ìdàpọ̀bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwujọ ní ilé Ọlọ́run.

15. Kí ikú kí ó dé bá wọn,Kí wọn ó lọ láàyè sí isà òkú,Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16. Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run; Olúwa yóò sì gbà mí.

17. Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sánèmi sunkún jáde nínú ìpọ́njú,o sì gbọ́ ohùn mi.

18. Ó rà mí padà láìléwukúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.

19. Ọlọ́run yóò gbọ́ yóò sì pọ́n wọn lójúàní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbà a nì—SelaNítorí tí wọn kò ní àyípadà,tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20. Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ Rẹ̀;ó ti bá májẹ̀mú Rẹ̀ jẹ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 55