Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 55:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:

2. Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo

3. Sí ohùn àwọn ọ̀ta ni,nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí miwọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

4. Ọkàn mi wà nínú ìrọra pẹ̀lú;ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.

5. Ìbẹ̀rù àti ìwàrírí wa sí ara mi;ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.

6. Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.

7. Èmi ìbá sá lọ jìnnà rérékí ń sì dúró sí ihà;

8. Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,jìnnà kúrò nínú ìjì àti èfúùfù líle.”

9. Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.

Ka pipe ipin Sáàmù 55