Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 55:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:

2. Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo

3. Sí ohùn àwọn ọ̀ta ni,nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí miwọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

4. Ọkàn mi wà nínú ìrọra pẹ̀lú;ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.

5. Ìbẹ̀rù àti ìwàrírí wa sí ara mi;ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.

6. Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.

Ka pipe ipin Sáàmù 55