Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 54:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbà mí, Ọlọ́run nípa orúkọ Rẹ:dá mi láre nípa agbára Rẹ.

2. Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run;fi etí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

3. Àwọn àlejò ń dìde sí mí.Àwọn aláìláàánú ènìyàn ń wá ayé miàwọn ẹni tí kò ka Ọlọ́run sí ní ojú wọn.

4. Kíyèsí i Ọlọ́run ni Olùrànlọ́wọ́ mi; Olúwa ní ẹni tí ó mú mi dúró,pa wọ́n run nínú òtítọ́ Rẹ.

5. Jẹ́ kí ibi padà sẹ́yìn sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi;pa wọ́n run nínú òtítọ́ Rẹ.

Ka pipe ipin Sáàmù 54