Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 53:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Asiwèrè wí ní ọkàn Rẹ̀ pé:“Ọlọ́run kò sí.”Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;kò sì sí ẹnìkan tí ń ṣe rere.

2. Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀runsórí àwọn ọmọ ènìyànláti wò bóyá ẹnìkan wà tí ó ní òye,tí ó sì ń wá Ọlọ́run.

3. Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.

4. Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹuntí wọn kò sì pe Ọlọ́run?

5. Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńláníbì tí ẹ̀rù kò gbé sínítorí Ọlọ́rún tí fọ́n egungun àwọn tí ó dótì ọ́ ká;ìwọ tí dójú tì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.

6. Ìgbàlà Ísírẹ́lì ìbá jáde wá láti Síónì!Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn Rẹ̀ padà,jẹ́ kí Jákọ́bù yọ̀ kí inú Ísírẹ́lì sì máa dùn!

Ka pipe ipin Sáàmù 53