3. Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
4. Sí ọ, ìwọ nìkan soso, ni mo sẹ̀ síni mo sì ṣe búburú níwájú Rẹ̀,kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọbá ń ṣe ìdájọ́.
5. Ní tòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
6. Ní tòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀ kọ̀.
7. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé ísópù, èmi yóò sì mọ́;fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju sínóò lọ.
8. Jẹ́ kí ń gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;jẹ́ kí gbogbo egúngún tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
9. Pa ojú Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mikí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédé mi rẹ́.