Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 51:3-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.

4. Sí ọ, ìwọ nìkan soso, ni mo sẹ̀ síni mo sì ṣe búburú níwájú Rẹ̀,kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọbá ń ṣe ìdájọ́.

5. Ní tòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.

6. Ní tòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀ kọ̀.

7. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé ísópù, èmi yóò sì mọ́;fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju sínóò lọ.

8. Jẹ́ kí ń gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;jẹ́ kí gbogbo egúngún tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.

9. Pa ojú Rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mikí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédé mi rẹ́.

10. Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.

11. Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú Rẹ̀kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ mi.

12. Mú ayọ̀ ìgbàlà Rẹ̀ tọ̀ mí wákí o sì fún mí ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13. Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ àwọn Olùrékọjá ní ọ̀nà Rẹ̀,àwọn ẹlẹ́sẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.

14. Gbàmí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo Rẹ kíkan.

15. Olúwa, sí mi ní ètè mi gbogbo,àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn Rẹ̀.

16. Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọọrẹ̀-ẹbọ sísun

Ka pipe ipin Sáàmù 51