Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 51:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Sàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bíìdúró sinsin ìfẹ́ Rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú Rẹ̀kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.

2. Wẹ gbogbo àìṣedédé mi nù kúròkí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

3. Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.

4. Sí ọ, ìwọ nìkan soso, ni mo sẹ̀ síni mo sì ṣe búburú níwájú Rẹ̀,kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọbá ń ṣe ìdájọ́.

5. Ní tòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.

6. Ní tòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀ kọ̀.

Ka pipe ipin Sáàmù 51