Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 50:8-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Èmi kí yóò bá ọ wínítorí àwọn ìrúbọ Rẹ̀tàbí ọrẹ̀ ẹbọ sísun Rẹ, èyí tí ó wà níwájú miní ìgbà gbogbo.

9. Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí ó kọ fún untàbí kí o mú ewúré látiinú agbo ẹran Rẹ̀

10. Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmíàti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.

11. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńláàti gbogbo ẹ̀dá alààyé tí ó wà ní orí ilẹ ni tèmi

12. Bí ebi tílẹ̀ ń pá mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbotí ó wa ní inú Rẹ̀.

13. Ǹjẹ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbímú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́?

14. Rú ẹbọ ọrẹ sí Ọlọ́runsan ẹ̀jẹ̀ Rẹ fún ọ̀gá ògo,

15. Kí o sì pe mí ni ọjọ́ ìpọ́njú,èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.

16. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọnènìyàn búburú:“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọtàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mu mi ní ẹnu Rẹ?

17. Ìwọ kórìíra àsẹ miìwọ sì sá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan

18. Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́-ọnìwọ sì da ara Rẹ̀ dé àwọn alágbèrè

19. Ìwọ lo ẹnu Rẹ̀ fún aburúìwọ sì ń fi ahọ́n Rẹ pète ẹ̀tàn

20. Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí ará-kun-rin Rẹ,ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá Rẹ jẹ́

21. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wíèmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara Rẹ.

22. “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́runBí bẹ́ ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹ́pẹ̀rẹ́láì sí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀

23. Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ ọpẹ́ bu ọláfún mi; kí ó sì tún ọ̀nà Rẹ̀ ṣekí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”

Ka pipe ipin Sáàmù 50