5. “Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún miàwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi”.
6. Àwọn ọ̀run sọ̀rọ̀ òdodo Rẹ̀,Nítorí òun fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́
7. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, èmi yóò jẹrìí sí ọ:èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run Rẹ.
8. Èmi kí yóò bá ọ wínítorí àwọn ìrúbọ Rẹ̀tàbí ọrẹ̀ ẹbọ sísun Rẹ, èyí tí ó wà níwájú miní ìgbà gbogbo.
9. Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí ó kọ fún untàbí kí o mú ewúré látiinú agbo ẹran Rẹ̀
10. Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmíàti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.