Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 50:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Rú ẹbọ ọrẹ sí Ọlọ́runsan ẹ̀jẹ̀ Rẹ fún ọ̀gá ògo,

15. Kí o sì pe mí ni ọjọ́ ìpọ́njú,èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.

16. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọnènìyàn búburú:“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọtàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mu mi ní ẹnu Rẹ?

17. Ìwọ kórìíra àsẹ miìwọ sì sá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan

18. Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́-ọnìwọ sì da ara Rẹ̀ dé àwọn alágbèrè

19. Ìwọ lo ẹnu Rẹ̀ fún aburúìwọ sì ń fi ahọ́n Rẹ pète ẹ̀tàn

20. Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí ará-kun-rin Rẹ,ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá Rẹ jẹ́

Ka pipe ipin Sáàmù 50