Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 5:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,kíyèsí àròyé mi.

2. Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,ọba mi àti Ọlọ́run mi,nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

3. Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;ní òwúrọ̀ èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú Rẹ̀èmi yóò sì dúró ní ìrètí.

4. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.

5. Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú Rẹ̀;ìwọ kóríra gbogbo àwọn aṣebi.

6. Ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run;apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyànni Olúwa yóò kórìíra.

7. Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú Rẹ̀,èmi yóò wá sínú ilé Rẹ̀;ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríbasí ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ̀.

8. Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo Rẹ,nítorí àwọn ọ̀ta mi,mú ọ̀nà Rẹ tọ́ níwájú mi.

9. Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;ọkàn wọn kún fún ìparun.ọ̀nà ọ̀fun wọn ni iṣà òkú tí ó sí sílẹ̀;pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.

10. Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!Jẹ́ kí rìkísí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

11. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.Tan ààbò Rẹ sórí wọn,àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ Rẹ yóò máa yọ̀ nínú Rẹ.

12. Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;ìwọ fi ojú rere Rẹ yí wọn ká bí àṣà.

Ka pipe ipin Sáàmù 5