Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 49:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Níti ki ó máa wà títí ayéláì rí ìsà òkú.

10. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kúbẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú sègbéwọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn

11. Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláéibùgbé wọn láti ìrandé ìranwọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn

12. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́o sì dàbí ẹranko tí o sègbé

13. Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ogbàgbọ́ nínú ara wọn,àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,tí o gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela

14. Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkúikú yóò jẹun lórí wọn;ẹni tí ó dúró ṣinṣin ní yóòjọba lórí wọn ní òwúrọ̀;Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.

15. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padàkúrò nínú isà òkúyóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara Rẹ̀.

16. Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnikan bá di ọlọ́rọ̀Nígbà tí ìyìn ilé Rẹ̀ ń pọ̀ síi

Ka pipe ipin Sáàmù 49