Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 49:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé

2. Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kérétalákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!

3. Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́nìsọ láti ọkàn mi yóò mú òye wá

4. Èmi yóò yí etí mi sí òweolókùn ni èmi yóò ṣi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mí sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

5. Èéṣé ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi déNígbà tí àwọn ènìyàn búburú àti ayan nijẹ yí mi ká,

6. Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọntí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọpọlọpọ ọrọ̀ wọn

7. Kò sí ọkùnrin tí o le ra ẹ̀mí ẹnìkejì Rẹ̀padà tàbí san owó ìràpadà fúnỌlọ́run.

8. Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ iyebíyekò sì sí iye owó tó tó fún sísan Rẹ̀

Ka pipe ipin Sáàmù 49