Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 48:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọn ríi bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́na yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ

6. Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí

7. Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Táṣíṣìwọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà oorùn.

8. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,Ní ìnú Olúwa àwọn ọmọ ogunNí ìlú Ọlọ́run waỌlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela

9. Láàrin tẹ́ḿpìlì Rẹ, Ọlọ́runàwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ Rẹ

10. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ Rẹ Ọlọ́runìyìn Rẹ̀ dé òpin ayéọwọ́ ọ̀tún Rẹ kún fún òdodo

11. Jẹ́ kí òkè Síónì kí ó yọ̀kí inú àwọn ọmọbìnrin Júdà kí ó dùnnítorí ìdájọ́ Rẹ̀.

12. Rìn Síónì kiri lọ yíká Rẹ̀,ka ilé ìsọ́ Rẹ̀

13. Kíyèsí odi Rẹ̀kíyèsí àwọn ààfin Rẹ̀kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀

14. Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayéÒun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Ka pipe ipin Sáàmù 48