Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 48:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹni ńlá ní Olúwa, tí o sì yẹ láti máa yìnní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ Rẹ̀

2. Ó dára nínú ipò ìtẹ́ Rẹ̀ayọ̀ gbogbo ayéòkè Síónì, ní ìhà àríwání ìlú ọba ńlá.

3. Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin Rẹ̀;ó fi ara Rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

4. Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ

5. Wọn ríi bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́na yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ

6. Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí

7. Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Táṣíṣìwọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà oorùn.

8. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,Ní ìnú Olúwa àwọn ọmọ ogunNí ìlú Ọlọ́run waỌlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela

9. Láàrin tẹ́ḿpìlì Rẹ, Ọlọ́runàwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ Rẹ

Ka pipe ipin Sáàmù 48