Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 45:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.

3. Gba idà Rẹ mọ́ ìhà Rẹ, ìwọ alágbára jùlọwọ ara Rẹ̀ ní ògo àti ọla ńlá.

4. Nínú ọlá-ńlá Rẹ máa gẹṣin lọ ní àlàáfíàlórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ṣe ohun ẹ̀rù

5. Jẹ́ kí ọfà mímú Rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lujẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀

6. Ìjọba Rẹ Ọlọ́run, yóò pẹ́ títí ayéọ̀pá aládé ni yóò jẹ́ ọ̀pá ìjọba Rẹ

7. Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburúnígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run Rẹ̀ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀,nípa fífí àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́

8. Gbogbo aṣọ Rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjíá àti alóe àti kaṣíà;láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣeorin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú Rẹ̀ dùn.

9. Àwọn ọmọbìnrin àwọn aládé wànínú àwọn àyànfẹ́ Rẹ̀ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúrónínú wúrà ófórì.

10. Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí Rẹ̀ símigbàgbé àwọn ènìyàn Rẹ àti ilé baba Rẹ

11. Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà Rẹ gidigidinítorí òun ni Olúwa Rẹkí ìwọ sì máa tẹríba fún un.

Ka pipe ipin Sáàmù 45