Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 45:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ọmọbìnrin ọba tirẹ̀ yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùnàwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojú rere Rẹ̀.

13. Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárin ilé Rẹ̀aṣọ ìbalẹ̀ Rẹ̀ a ṣe é lọ́sọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà

14. Nínú aṣọ ìbànújẹ́ iyebíye ni a mú-un wá sí ọ̀dọ̀ ọbaàwọn wúndíá ẹgbẹ́ Rẹ̀ tẹ̀ lé e wọ́n, sí mú-un tọ̀ ọ́ wá

15. Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùnwọ́n sì wọ ààfin ọba.

16. Ọmọ Rẹ̀ ni yóò gba ipò baba Rẹ̀ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.

Ka pipe ipin Sáàmù 45