Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 45:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ reregẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohuntí mo ti ṣe fún ọbaahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.

2. Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.

3. Gba idà Rẹ mọ́ ìhà Rẹ, ìwọ alágbára jùlọwọ ara Rẹ̀ ní ògo àti ọla ńlá.

4. Nínú ọlá-ńlá Rẹ máa gẹṣin lọ ní àlàáfíàlórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún Rẹ ṣe ohun ẹ̀rù

5. Jẹ́ kí ọfà mímú Rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lujẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀

Ka pipe ipin Sáàmù 45