Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 44:4-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jákọ́bù.

5. Nípaṣẹ̀ Rẹ̀ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣúbú; nípasẹ̀ orúkọ Rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá ti ó dìde sí wa mọ́lẹ̀

6. Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun miidà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,

7. Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.

8. Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,àwa ó sì yin orúkọ Rẹ̀ títí láé. Sela

9. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá;Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.

10. Ìwọ ti bá wa jàìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,àwọn ọ̀ta wa ti gba ilẹ̀ wa,wọ́n sì fi ipá gba oko wa.

11. Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntànÌwọ sì ti tú wa ká sí àárin àwọn aláìkọlà.

12. Ìwọ ta àwọn ènìyàn Rẹ fún owó kékeré,Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

13. Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.

14. Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.

15. Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,

16. nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tànní ojú àwọn ọ̀ta àti olùgbẹ̀san.

17. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,ṣíbẹ̀ àwa kò gbàgbé Rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mu Rẹ̀.

18. Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà Rẹ̀.

19. Ṣùgbọ́n wọ́n kọ lù wá,ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ajákotí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20. Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run watàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.

21. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí Rẹ̀,níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kò inú ọkàn?

22. Ṣíbẹ̀, nítorí Rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojojúmọ́a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23. Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?Dìde fún ra Rẹ! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.

Ka pipe ipin Sáàmù 44