Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 44:21-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí Rẹ̀,níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kò inú ọkàn?

22. Ṣíbẹ̀, nítorí Rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojojúmọ́a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23. Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?Dìde fún ra Rẹ! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.

24. Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú Rẹ mọ́tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?

25. Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.

26. Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;ràwápadà nítorí ìfẹ́ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

Ka pipe ipin Sáàmù 44