Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 44:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àti fi ètí wa gbọ́, Ọlọ́runàwọn baba wa tí sọ fún waoun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.

2. Ìwọ fi ọwọ́ Rẹ̀ lé orílẹ̀-èdè jádeÌwọ sì gbin àwọn baba wa;Ìwọ run àwọn ènìyàn náàÌwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.

3. Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọn gba ilẹ̀ náà,bẹ́ẹ̀ ni kì í se apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò se;ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti, apá Rẹ̀;àti ìmọ́lẹ̀ ojú Rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

4. Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jákọ́bù.

5. Nípaṣẹ̀ Rẹ̀ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣúbú; nípasẹ̀ orúkọ Rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá ti ó dìde sí wa mọ́lẹ̀

6. Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun miidà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,

7. Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.

8. Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,àwa ó sì yin orúkọ Rẹ̀ títí láé. Sela

9. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá;Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.

10. Ìwọ ti bá wa jàìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,àwọn ọ̀ta wa ti gba ilẹ̀ wa,wọ́n sì fi ipá gba oko wa.

11. Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntànÌwọ sì ti tú wa ká sí àárin àwọn aláìkọlà.

12. Ìwọ ta àwọn ènìyàn Rẹ fún owó kékeré,Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

13. Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.

14. Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.

15. Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,

Ka pipe ipin Sáàmù 44