Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 43:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dámiláre, Ọlọ́run mi,kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè aláìwà-bí-Ọlọ́run:yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.

2. Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?

3. Ran ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ jáde,jẹ́ kí wọn ó máa dààbò bò mí;jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ Rẹ,sí ibi tí ìwọ ń gbé.

4. Nígbà náà ní èmi o lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,sí Ọlọ́run ayọ̀ mí àti ìdùnnú mi,èmi yóò yin ọ pẹ̀lú dùùrù,ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

5. Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?Fi ìrètí Rẹ sínú Ọlọ́run,nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun niOlùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 43