Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 41:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;èmi ni wọn ń gbìmọ̀ ibi sí,

8. wọ́n wí pé “Ohun búburú ni ó di mọ́-ọn sinsinàti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,kì yóò dìde mọ́”.

9. Pàápàá ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,tí gbé gìgíṣẹ̀ Rẹ̀ sókè sí mi.

10. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.

11. Èmi mọ̀ pé inú Rẹ̀ dùn sí mi,nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.

12. Bí ó ṣe tèmi niìwọ dì mí mú nínú ìwà òtítọ́ miìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú Rẹ títí láé.

13. Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lìláé àti láéláé.Àmín àti Àmín.

Ka pipe ipin Sáàmù 41