Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 41:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mí;wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.

5. Àwọn ọ̀ta mi ń sọ́rọ̀ mi nínú arankan, pé“Nígbà wo ni yóò kú ti orúkọ Rẹ̀ yóò sì run?”

6. Nígbà kígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà Rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara Rẹ̀;nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kalẹ̀.

7. Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;èmi ni wọn ń gbìmọ̀ ibi sí,

8. wọ́n wí pé “Ohun búburú ni ó di mọ́-ọn sinsinàti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,kì yóò dìde mọ́”.

9. Pàápàá ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,tí gbé gìgíṣẹ̀ Rẹ̀ sókè sí mi.

10. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.

11. Èmi mọ̀ pé inú Rẹ̀ dùn sí mi,nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.

Ka pipe ipin Sáàmù 41